Ìjẹ́wọ́ Ìnàkí Shìnágawà Kan
Láti Ọwọ́ Haruki Murakami (New Yorker (© June 2020)
Tí Kọ́lá Túbọ̀sún túmọ̀
Mo pàdé alàgbà ìnàkí yìí nílé ìtura Japaní kan nínú ilé-ìwẹ̀ onísun-gbígbóná kan ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Gunmà, ní bíi ọdún márùún sẹ́yìn. Ilé ìtura náà ti gbó, tàbí ká ní ó ti ń d’àlàpà. Kò fẹ́ẹ̀ lè dá dúró, mo kàn ní kí n sun’run alẹ́ kan níbẹ̀ ni.
Lásìkò yìí, mo ń rìnrìn àjò káàkiri ni, lọ síbikíbi tí ẹ̀mí bá darí mi sí. Nígbà tí mo sì dé ìlú onílé-ìwẹ̀ onísun-gbígbóná yìí, tí mo sì sọ̀ kalẹ̀ láti orí ọkọ̀-ojú-irin, aago méje alẹ́ ti kọjá. Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti fẹ́ parí, oòrùn ti wọ̀ tipẹ́, ibẹ̀ sì wà lábẹ́ òkùnkùn dúdú oní búlù irú èyí tí a máa ń rí láwọn ìlú orí-òkè. Ìjì olótùútù tó jánilárajẹ kan fẹ́ sísàlẹ̀ láti orí òkè wá, ó sì ń darí àwọn ìràwé tó dàbí ẹ̀ṣẹ́ ọwọ́ sílẹ̀, sójú ọ̀nà.
Mo rìn kọjá láàárín gbùngbùn ìlú onísun-gbígbóná yìí láti wá ibi wọ̀ sí ṣùgbọ́n kò sí ìkankan nínú àwọn ilé ìtura gidi níbẹ̀ tó fẹ́ gbàlejo lẹ́yìn àsìkò oúnjẹ alẹ́. Mo yà ní ibi márùún tàbí mẹ́fà ṣùgbọ́n gbogbo wọn ló já mi kulẹ̀. Ìgbà tó yá, ní agbègbè aṣálẹ̀ kan lẹ́yìn ìlú, mo ṣàbápàdé ilé ìtura kan tó gbà mí, tí kò sì ní gbowó oúnjẹ alẹ́. Ilẹ́ ìtura náà dàbí ibi tí a kọ̀ sílẹ̀, ibi jákujàku kan tí a lè pè ní gbàjẹ́nsinmi. Ilé náà ti fojúrí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn lọ, ṣùgbọ́n kò ní irú ọ̀yàyà tí èèyàn máa retí lọ́wọ́ ibùgbé àtijọ́ bíi tiẹ̀. Àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ ara ilé ò farajọra, wọ́n sì tún wọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ bíi pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tún àwọn nǹkan díẹ̀ ṣe níbẹ̀ ni. Kò dá mi lójú pé ó lè yèbó lọ́wọ́ ìmìtìtì tó bá tún ṣẹ̀lẹ̀, mo si tètè ń gbàdúrà pé kí ìmìtìtì ilẹ̀ kankan má ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yìí tàbí òmíràn.
Wọn kò fún wa lóńjẹ alẹ́, ṣùgbọ́n oúnjẹ àárọ̀ wà níbẹ̀, owó oorun ọjọ́ kan ò sí wọ́n rárá. Lẹ́nu ọ̀nà ni tàbìlì ìgbàlejò kan, tí ọkùnrin arúgbó apárí kan wà lẹ́yìn ẹ — kò nírun ìpéǹpéjú pàápàá — ó sì gba owó alẹ́ kejì dání. Àìnírun ìpéǹpéjú yìí jẹ́ kójú arúgbókùnrin yìí dàbí èyí tó mọ́lẹ̀ ní gbàgede lọ́nà àràmọ̀ndà. Ológbó ńlá dúdú kan, tóun náà darúgbó, wa níjokòó lórí fùkùfùkù kan lẹ́gbẹ́ẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé nǹkankan ṣeé nímú, torí pé ó ń hanrun pẹ̀lú ariwo ju ti olóngbò kankan tí mo ti gbọ́ rí lọ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìmísókè-mísódò ẹ̀ á dákẹ́ iṣẹ́ díẹ̀. Gbogbo nǹkan tó wà nínú ilé ìtura yìí ló dàbí oun tó ti dàgbá, dògbó, tó sì ń fàya díẹ̀díẹ̀.
Yàrá tí wọ́n fi mí sí kéré, ó dàbíi yàrá ẹrù tí wọ́n máa ń kó aṣọ ìbora ibùsùn sí. Iná orí àjà ò mọ́lẹ̀ púpọ̀, igi ìtẹ́lẹ̀ abẹ́ ẹní tatami ń dún bíi pó fẹ́ wó pẹ̀lú ìgbésẹ́ kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ jù báyìí láti kọbiara sí èyí. Mo sọ fúnra mi pé ó yẹ kínú mi dùn pé mo tiẹ̀ rí òrùlé sórí mi àti ibùsùn láti sùn lé.
Mo gbé àpò èjìká mi, ẹrù kan ṣoṣo tí mo ní, sílẹ̀, mo sì gba inú ìlú lọ (kìí ṣá ṣe irú inú yàrá tí èèyàn ti máa ń gbafẹ́ nìyí). Mo lọ sínú ìsọ núdùlù sóbà kan nítòsí mo sì jẹun alẹ́ kékeré. Kò sí irú ilé oúnjẹ mìíràn ní ṣíṣí, nítorí náà, èyí nìkan ni tàbí kí n pebi sùn. Mo mu bíà, ìpápánu díẹ̀, àti sóbà gbígbóná. Sóbà ọ̀hún ò fi bẹ́ẹ̀ dáa, ọbẹ̀ náà lọ́wọ́rọ́, ṣùgbọ́n sẹ́, mi ò ṣetán láti bínú. Ó ṣáà dáa ju sísunlébi lọ. Nígbà tí mo kúrò nísọ̀ sóbà, mo rò pé ki n ra ìpanu diẹ̀ àti ìgò wisikí kan, ṣùgbọ́n mi ò rí ibi tí wọ́n ti ń tàá. Èyí jẹ́ lẹ́yìn aago mẹ́jọ, nítorínáà àwọn bíi ìsọ̀ kékèké tán ti ń yìnbọn tí a máa ń rí ní irú àwọn ìlú onísun-gbígbóná nìkan ló wà ní ṣíṣí. Nítorínáà, mo sáré padà sínú ilé ìtura, mo yí aṣọ mi padà sí yukata, mo sì lọ sísàlẹ̀ láti lọ wẹ̀.
Yàtọ̀ sí jákujàku ilé náà àti àwọn nǹkan inú ẹ̀, ìwẹ̀ orísun-gbígbóná nínú ilé ìtura náà dùn púpọ̀ lọ́nà tó yanilẹ́nu. Omi ìwẹ̀ gbígbóná náà jẹ́ àwọ̀ ewé tó nípọn, tí wọn ò tíì ṣàmúlùmálà ẹ̀, òórùn sọ́lfọ̀ ẹ̀ tó ń ta ni nímú ju nǹkankan tí mo ti rírí; mo sì jókòó sínú ẹ̀, mo ń mú ara mi gbádùn wọnú egungun. Kò sí ẹlòmíì níbẹ̀ tó ń wẹ̀ (mi ò tiẹ̀ mọ̀ bóyá ẹnikankan mìíràn tiẹ̀ ń gbé inú ibẹ̀ yàtọ̀ s’émi), mo sì le farabalẹ̀ gbádùn ìwẹ̀ mi ní púpọ̀ ìbàlẹ̀ọkàn. Nígbà tó ṣe díẹ̀, orí mi ń fúyẹ́ díẹ̀, mo sì jáde láti lọ gbatẹ́gùn níta. Ìgbà tó yá, mo padà sínú balùwẹ̀. Bóyá yíyan ilẹ́ ìtura kékeré òburẹ́wà yìí jẹ́ ìpinnu gidi lẹ́yìnọ̀rẹyìn, mo rò. Ó ṣáà jẹ́ èyí tó fini lọ́kàn balẹ̀ ju wíwẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ arìnrìnàjò aláriwo kankan lọ, bíi ti àwọn ilé ìtura ńlá.
Mo wà nínu omi ìwẹ̀ ní balùwẹ̀ fún ìgbà ìkẹta nígbà tí ìnàkí yìí ṣílẹ̀kùn pẹ̀lú ariwo, tó sì wọlé. “Ẹ má bìnú o,” ó sọ lóhùn ilẹ̀. Ó gbà mí lásìkò díẹ̀ láti ríi pé ìnàkí ni. Gbogbo omi kíki gbígbóná yẹn ti mú ojú mi pòòyì, mi ò sì lè láíláì rò pé mo lè gbọ́ kí ìnàkí sọ̀rọ̀, nítorínáà, mi ò tètè ṣe àsopọ̀ pẹ̀lú ohun tí mo ń rí àti ìdánilójú pé ìnàkí gangan nìyí. Ọpọlọ mi fọ́nká bí mo ṣe ń ranjú láti inú híhó omi ìwẹ̀ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, mọ́ ìnàkí náà tó pa ilẹ̀kùn gílásì dé lẹ́yìn ẹ̀. Ó tún àwọn garawa kékèké tó wà káàkiri nílẹ̀ tò, ó sì fi tẹ̀mómítà kan sínú omi ìwẹ̀ mi láti wo bó ṣe gbóná tó. Ó tẹjú mọ́ ọwọ́ ojú tẹ̀mómítà yìí, ojú ẹ̀ súnkì bí dókítà kòkòrò ààrùn tó ń ṣe ìyapa àjàkálẹ̀ kékeré tuntun kan.
“Báwo nìwẹ̀ yín náà?” Ìnàkí yìí bèèrè lọ́wọ́ mi.
“Ó dáa púpọ̀, ẹ ṣé,” Mo dáhùn. Ohùn mi gbọ̀nrìrì nípẹ̀lẹ́kùtù nínú ooru omi gbígbóná yìí. Ó fẹ́ẹ̀ lè jọ ìró bí idán. Kò dàbíi pé ara mi ló ti jáde wá; ó dàbí ohùn jìnàréré kan tó padà wá láti ìgbà ẹ̀yìnwá, láti inú igbó jíjìn. Ohùn jìnàréré ọ̀hún ni… e tiẹ̀ dúró ná. Kíni ìnàkí ń ṣe níbi? Kílósìdé tó fi ń sọ èdè èèyàn?
“Ṣé kí n báa yín yún ẹ̀yìn yín?” Ìnàkí náà bèèrè, ohùn ẹ̀ lọ sísàlẹ̀ síi. Ó ní ohùn tó mọ́, tó sì fanimọ́ra bíi t’akọrin doo-wop. Kìí ṣe oun tí èèyàn lérò. Ṣùgbọ́n kò sí nǹkan tó ṣe kàyéfì nípa ohùn ẹ̀, dé bi pé tí o bá dijú tí o sì tẹ́tí, wàá rò pé ènìyàn lásán kan ló ń sọ̀rọ̀ ni.
“Bẹ́ẹ̀ni, ẹ ṣé,” mo fèsì. Kìí ṣá ṣe pé mo jókòó síbẹ̀ pẹ̀lú èrò pé ẹnìkan á wá bá mi yún ẹ̀yìn mi, ṣùgbọ́n mo bẹ̀rù pé tí mo bá kọ̀ọ́, ó lè rò pé mo lòdì sí pé kí ìnàkí kankan bá mi fọ ara mi ni. Ṣèbí kò fi ṣè’kà, mo ròó sínú, mi ò sì fẹ́ mú inú ẹ̀ bàjẹ́. Nítorínáà mo dìde ní pẹ̀lẹ́kùtù kúrò nínú balùwẹ̀, mo gbé ara mi sílẹ̀ lórí pakó kékeré, mo sì kọ ẹ̀yìn mi sí ìnàkí yìí.
Ìnàkí yìí kò láṣọ kankan lára. Ṣèbí bó ṣe máa ń rí fún ìnàkí nìyí, nítorínáà, eléyìí kò yà mí lẹ́nu. Ó dàbíi pé ìnàkí náà ti darúgbó díẹ̀, ó sì ní funfun púpọ̀ lára àwọn irun ẹ̀. Ó mú aṣọ ìnura kékeré kan wá, ó fi ọṣẹ síi, ó sì bá mi fọ ara mi pẹ̀lú ọwọ́ tó mọṣẹ́.
“Òtútù ti ń mú lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́,” ìnàkí yìí sọ síta.
“Bẹ́ẹ̀ni.”
“Kó tó pẹ́, gbogbo ibí ni ìrìdídì á ti ya bò. Wọ́n á wá ní láti fi ọkọ́ gbá yìnyín láti orí àwọn òrùlé — kìí ṣe iṣẹ́ ọ̀lẹ, dájúdájú.”
Ìdákẹ́jẹ́ díẹ wà, ni mo bá bẹ́ wọlé. “Ìyẹn ni wípé ẹ lè sọ èdè ènìyàn?”
“Bẹ́ẹ̀ni,” ìnàkí náà dáhùn ní ṣókí. Ó ní láti jẹ́ pé wọ́n máa ń bèèrè èyí lọ́wọ́ ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. “Àwọn ènìyàn ló wò mí dàgbà ni, kí ń tó mọ̀, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Mo gbé fún ìgbà pípẹ́ ní Tokyo, ní Shìnágáwà.”
“Apá ibo ní Shìnágáwà?”
“Lágbègbè Gotenyama.”
“Àdùgbó tó dáa nìyẹ̀n.”
“Bẹ́ẹ̀ni, bẹ́ẹ ṣe mọ̀, ó jẹ́ ibi tó dára láti gbé. Lẹ́gbẹ́ẹ̀ ni Ọgbà Gotenyama, mo si gbádùn bójú ọjọ́ ṣe rí níbẹ̀.”
Ìtàkurọ̀sọ wa wá dúró díẹ̀ báyìí. Ìnàkí náà tẹ̀síwájú ní kánmọ́ láti fọ ẹ̀yìn mi (èyí tí mo gbádùn), ṣùgbọ́n ní gbogbo àsìkò yìí mo ń gbìyànjú láti ro gbogbo oun tó ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú làákáàyẹ̀. Ìnàkí tí a tọ́ dàgbà ní Shìnágáwà? Ọgbà Gotenyama? Tó ń sọ̀rọ̀ geere pẹ̀lú èdè ènìyàn. Báwo lèyí ṣe ṣẹlẹ̀? Ìnàkí nìyí nítorí ọlọ́run. Ọ̀bọ lásán-lásàn.
“Mo ń gbé ní Minato-ku,” mo sọ, èyí tó jẹ́ gbólóhùn tí kò ní ìtumọ̀ kankan.
“A tiẹ̀ fẹ́ẹ̀ jẹ́ alábàágbélé nìyẹn,” ìnàkí náà sọ lóhùn ọ̀rẹ́.
“Irú èèyàn wo ló tọ́ ẹ dàgbà ní Shìnágáwà?” Mo bèèrè.
“Ọ̀gá mi jẹ́ olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Ó jẹ́ olùmọ̀ràn ẹ̀kọ́ físísì, ó sì jẹ́ alága kan ní Ifáfiti Tokyo Gakugei.”
“Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ni nígbàyẹn.”
“Bẹ́ẹ̀ gaan ló jẹ́. Ó fẹ́ràn orin ju nǹkan mìíràn lọ, papàá jùlọ orin Bruckner àti Richard Strauss. Nítorí èyí lèmi náà fi nífẹ̀ẹ́ àwọn orin yẹn. Mo máa ń gbọ́ọ ní gbogbo ìgbà nígbà tí mo wà ní kékeré. A lè wípé mo gba ìmọ̀ ẹ̀ wọlé láì tiẹ̀ mọ̀.”
“Ẹ gbádùn Bruckner?”
“Bẹ́ẹ̀ni. Sínfónì Keje ẹ̀. Mo ti máa ń rí ìrìsí kẹta ẹ gẹ́gẹ́ bí oun tó ń múnú dùn.”
“Sinfónì Kẹsàán ẹ̀ ni mo máa ń sábà gbọ́,” mo sọ. Gbólóhùn mìíràn tí kò nítumọ̀.
“Bẹ́ẹ̀ni, orin tó ládùn gan ni,” ìnàkí náà sọ.
“Ìyẹn ni wípé ọ̀jọ̀gbọ́n yẹn ló kọ́ ẹ lédè?”
“Òun ni. Kò bímọ kankan. Bóyá nítorí ìyẹn ló ṣe kọ́ mi dáadáa ní gbogbo ìgbà tó bá ní àsìkò. Ó jẹ́ onísùúrù, ènìyàn tó nífẹ̀ẹ́ ètò àti ọgbọgba lórí ohunkóhun. Ó jẹ́ ẹ̀nìyàn tí kò gba gbẹ̀rẹ́ tó fẹ́ràn láti máa sọ pé títẹnumọ́ oun tó jẹ́ òtítọ́ ni ọ̀nà òdodo sí ọgbọ́n. Ìyàwó ẹ̀ jẹ ẹni tútù, dídùn, tó máa ń yọ́nú sí mi ní gbogbo ìgbà. Àwọn méjèèjì mọ ọwọ́ ara wọn. Mi ò fẹ́ sọ eléyìí fún ará ìta ṣùgbọ́n, ẹ gbà mí gbọ́, eré alẹ́ wọn máa ń gbomimu gidi.”
“Sé nítòótọ́?” Mo dáhùn.
Ìnàkí náà parí fífọ ẹ̀yìn mi nígbà tó yá. “Ẹ kúu sùúrù,” ó sọ, ó sì tẹríba.
“Ẹ ṣé,” mo dáhùn. “Ó dùn mọ́ mi gidi. Ìyẹn ni pé ilé ìtura yìí lẹ ti ń ṣiṣẹ́?”
“Bẹ́ẹ̀ni. Ojú àánú ni wọ́n ṣe fún mi láti máa ṣiṣẹ́ níbí. Àwọn ilé ìtura ńlá ojúlówó ò lè láíláí fún ìnàkí níṣẹ́. Ọ̀wọ́ iṣẹ́ kìí pọ̀ tó níbí, nítorínáà, tóo bá lè ṣe ìrànlọ́wọ́ díẹ̀díẹ̀ láyìíká, wọn ò kọ̀ bóo bá jẹ́ ìnàkí tàbí nǹkan mìíràn. Nítoríi pé mo jẹ́ ìnàkí, owó kékeré ni mo ń gbà. Wọn ò sì jẹ́ kí n ṣiṣẹ́ àfi níbi tí ẹnìkankan ò ti ní rí mi. Màá bá àwọn èèyàn tún balùwẹ̀ wọn ṣe, màá nulẹ̀, irú àwọn nǹkan báyìí. Nítorípé kò sí ẹni tí ìnàkí á gbé tíì fún tí kò ní yà lẹ́nu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Mi ò lè ṣiṣẹ́ nínú ilé ìdáná náà, nítorípé àá ní láti dojúkọ Òfin Ìmọ́tótó Oúnjẹ.”
“Ṣé ẹ ti ń ṣiṣẹ́ níbí fún ìgbà pípẹ́?” Mo bèèrè.
“Ó ti tó bí ọdún mẹ́ta.”
“Ṣùgbọ́n o, ẹ̀ẹ́ ti gba inú oríṣiríṣi nǹkan kọjá kẹẹ tó tẹ̀dó síbí o?”
Ìnàkí náà kan orí mọ́lẹ̀ ní kánmọ́. “Òótọ́ ni.”
Mo dúró díẹ̀, mo wá bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀, “Tí ò bá le jù o, ǹjẹ́ ẹ lè sọ fún mi díẹ̀ nípa ìpilẹ̀ yín?”
Ìnàkí náà rò èyí díẹ̀, o wá ní, “Bẹ́ẹ̀ni, kò sí ìyọnu. Ó lè má jọ yín lójú púpọ̀ tó bẹ́ẹ ṣe ròó, ṣùgbọ́n mo máa parí iṣẹ́ láago mẹ́wàá. Mo lè wá sí yàrá yín lẹ́yìn ìyẹn. Ǹjẹ́ eléyìí dáa?
“Dájúdájú,” mo fèsì. “Inú mi á dùn tí ẹ bá lè mú ọtí bíà díẹ̀ wá nígbà yẹn.”
“Mo ti gbọ́. Màá mú bíà tútù díẹ̀ wá. Ṣé Sapporo dáa?”
“Ìyẹn náà dáa. Ṣé pé ẹ máa ń mu bíà?”
“Díẹ̀, bẹ́ẹ̀ni.”
“Ó dáa, ẹ mú ìgò ńlá méjì wá nígbà yẹn.”
“Dájúdájú. Tó bá yé mi dáadáa, iyàrá Araiso lórí àjà kejì lẹ ń gbé?”
Bẹ́ẹ̀ni, mo sọ.
“O tiẹ̀ yanilẹ́nu, àb’ẹ́ẹ̀ ríi?” ìnàkí náà sọ. “Ilé ìtura kan láàrín òkè pẹ̀lú yàrá tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Araiso — “Etí Òmi Oníjọ̀gbọ́n.” Ó rẹ́rìín. Ní gbogbo ayé mi, mi ò tíì ríi kí ìnàkí rẹ́rìín rí. Ṣùgbọ́n mo rò pé àwọn ìnàkí máa ń rẹ́rìín, tàbí sùnkún, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ṣá. Kò yẹ kó yà mí lẹ́nu; ṣeb’óun náà ló ń sọ̀rọ̀ yìí.
“Kí n tó gbàgbé, ǹjẹ́ o tìẹ lórúkọ?” Mo bèèrè.
“Rárá, mi ò fi bẹ́ẹ̀ ní. Ṣùgbọ́n gbogbo èèyàn ló ń pè mí ní Ìnàkí Shìnágáwà.”
Ìnàkí náà ṣí ilẹ̀kùn onigíláàsì sí ibi balùwẹ̀, ó yípadà, ò tẹríba lọ́nà ìbọ̀wọ̀fún, ó sì pa ilẹ̀kùn dé ní pẹ̀lẹ́kùtù.
Ó TÓ DÍẸ̀ LẸ́YÌN AAGO MẸ́WÀÁ nígbà tí ìnàkí yìí dé sí yàrá Araiso, pẹ̀lú tíréè kan tó ní ìgò bíà ńlá lórí. (Bó ṣe wí, mi ò mọ ìdí tí wọ́n fi pè yàrá náà ní “Etí Omi Oníjọ̀gbọ̀n” — àwọn ilé ìtura Japaní sábà máa n sọ àwọn yàrá wọn kọ̀ọ̀kan lórúkọ, ṣùgbọ́n síbẹ̀, ó ṣì jẹ́ yàrá tí kò dún-ún wò lójú, tó dàbí yàrá ìkóǹkanpamọ́sí tí kò ní nǹkankan lára láti mú ni rántí orúkọ ẹ̀.) Lẹ́yìn bíà náà, tíréè náà ní oun ìṣígò, gíláàsì méjì, pẹ̀lú àwọn ìpanu díẹ̀ — ẹja odò gbígbẹ tí a yíláta àti àpò ìpápánu Kapipi — bisikí onírẹsì kékèké pẹ̀lú ẹ̀pà. Irú àwọn oun tí a máa ń rí jẹ nílé ọtí. Ìnàkí yìí jẹ́ èyí tó kọjúmọ́ṣẹ́ gidi.
***
ÌNÀKÍ NÁÀ TI WỌṢỌ BÁYÌÍ, nínú bùbá tí a tẹ Mo <3 NY sórí ẹ̀, pẹ̀lú ṣòkòtò ìṣeré aláwọ̀ eérú, bóyá irú èyí tí ọmọdé kan ti lò kù.
Kò sí tábìlì kankan nínú yàrá yìí, nítorínáà a jókòó, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wa, lórí kúṣínì zabuton, a sì fẹ̀yìnti ògiri. Ìnàkí yìí fi ópúnà ṣí ìdérí ìkan nínú àwọn bíà náà, ó sì dàá sínú ife gílásì méjì. Láìsọ̀rọ̀, a fi ìfe gíláàsì wa kanra lọ́nà ìfẹ́.
“Ẹ ṣé fún ọtí yìí,” ìnàkí náà sọ, ó sì fi tìdùnnú-tìdùnnú da ọtí tútù náà sọ́fun. Mo mu díẹ̀ fúnra mi náà. Ká má parọ́, ó ṣe ni ní kàyéfì bí mo ṣe wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìnàkí tí a jọ ń pín bíà mu, ṣùgbọ́n ó mọ́ra nígbà tó yá.
“Kò sí oun tó dáa tó kí èèyàn mu bíà lẹ́yìn iṣẹ́,” ìnàkí náà sọ, ó sì ń fi ẹ̀yìn ọwọ́ onírun ẹ̀ nu ẹnu. “Ṣùgbọ́n torí mo jẹ́ ìnàkí, àǹfàní láti mu bíà báyìí kìí sábà yọjú rárá.”
“Ṣé níbí lẹ ń gbé ni, nibi iṣẹ́ yìí?”
“Bẹ́ẹ̀ni, yàrá kan wà, bíi àjà, níbi tí wọ́n jẹ́ kí n sùn sí. Àwọn eku máa ń wá síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀kan, nítorínáà, ó nira púpọ̀ láti farabalẹ̀ sinmi níbẹ̀, ṣùgbọ́n ìnàkí ni mí, mo ní láti máa dúpẹ́ ni pé mo rí ibùsùn sùn sí, àti oúnjẹ tó péye mẹ́ta lójúmọ́… Ìyẹn kìí ṣe pé eléyìí jẹ́ párádísè o.
Ìnàkí náà ti parí ife bíà àkọ́kọ́ ẹ̀, nítorínáà, mo bu èmíì fúun.
“Ẹ ṣé,” ó sọ pẹ̀lú ọ̀wọ̀.
“Ǹjẹ́ ọ̀dọ̀ ènìyàn nìkan lẹ ti ń gbé rí ni, àbí ẹ ti gbé lọ́dọ irú àwọn tiyín? Pẹ̀lú àwọn ìnàkí mìíràn fún àpẹẹrẹ?” Mo bèèrè. Nǹkan pọ̀ púpọ̀ tí mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀.
“Bẹ́ẹ̀ni, nígbà púpọ̀,” ìnàkí náà dáhùn. Ojú ẹ̀ ṣú díẹ̀. Àwọn rírún ẹ̀gbẹ́ ojú ẹ̀ hunjọ lọ́nà jíjìn. “Fún oríṣiríṣi ìdí, wọ́n lé mi jáde, ní tipátipá, láti Shìnágáwà, wọ́n sì tú mi sílẹ̀ sí Takasakiyama, àdúgbò gúsù tó lókìkí fún pápá ìṣeré àwọn ìnàkí. Mo kọ́kọ́ rò pé mo lè gbé lálàáfíà níbẹ̀ ni, ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ kọ́ ló rí. Àwọn ìnàkí yòókù tó wà níbẹ̀ jẹ́ ará mi, ẹ má ṣì mí gbọ́, ṣùgbọ́n nítorípé ilé ọmọ ènìyàn la ti wò mí dàgbà, lọ́wọ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àti ìyàwó ẹ̀, mi ò lè fi èrò mi hàn fún wọn dáadáa. A ò jọ’ra wa púpọ̀ rárá, ìjíròrò kò sì rọrùn. ‘O ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó panilẹ́rìín,’ wọ́n sọ fún mi, wọ́n sì fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì kanra mọ́ mi. Àwọn obìnrin ìnàkí máa ń rẹ́rìín tán bá wò mí. Ìyàtọ̀ kékèké máa ń kan àwọn ìnàkí lára gidi. Wọ́n rí bí mo ṣe ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ohun tó panilẹ́rìín, ó sì mú inú bí wọn. Ó ni wọ́n lára nígbà míì. Èyí mú kó le fún mi láti gbé pẹ̀lú wọn, nítorínáà mo gbọ̀nà tèmi lọ. Mo di ìnàkí alákatakítí lọ́rọ̀ kan.”
“Èyí gbọdọ̀ máyé le fún ẹ o.”
“Bẹ́ẹ̀ gan ló rí. Kò sẹ́ni tó dáàbò bò mí, mo ní láti wá oúnjẹ lọ fúnra mi kí n lè ráyé gbé. Ṣùgbọ́n èyí tó burú jù ni tàìrẹ́ni bá sọ̀rọ̀pọ̀. Mi ò lè bá àwọn ìnàkí sọ̀rọ̀, tàbí àwọn ènìyàn. Dídánìkangbé báyìí ń banilọ́kànjẹ́. Takasakiyama kún fún àwọn àlejò ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé mo kàn lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí mo bá pàdé lójú ọ̀nà. Tí mo bá ṣe eléyìí, gbogbo wàhálá ló máa dá sílẹ̀. Àtubọ̀tán ẹ̀ ni pé mo wá wà láàárín agbedemejì, ìnàkí táa kọ̀sílẹ̀, tí kìí ṣe alábàágbépọ̀ àwọn ènìyàn, tí kìí síì ṣara agbègbè àwọn ìnàkí. Ayé tó nira gbáà ni.”
“Oò sì lè gbọ́ Bruckner náà rárá, àbi?”
“Bẹ́ẹ̀ni. Ìyẹn kìí ṣe ara ayé mi mọ́ báyìí,” Ìnàkí Shìnágáwà náà sọ, ó sì mu bíà díẹ̀ síi. Mo ṣọ́ ojú ẹ̀ wò, ṣùgbọ́n nítorípé ó ti pupa tẹ́lẹ̀, mi ò ríi pé ó tún ti pupa síi. Mo níran pé ìnàkí yìí ní ìjánu nínu mímu ọtí ẹ̀. Àbí bóyá pẹ̀lú àwọn ìnàkí, èèyàn kìí mọ̀ láti ojú wọn tí wọ́n bá ti yó ni.
“Nǹkan mìíràn tó máa ń bà mí nínú jẹ́ ni ìbálòpọ̀ pẹ̀lú abo.”
“Ṣé tòótọ́?” mo bèèrè. “Ìgbà tẹ́ẹ sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, ìtumọ̀ èyí ni pé— ”
“Ní ṣókí, ara mi kìí dìde rárá fún àwọn abo ìnàkí. Mo ní orísiríṣi àǹfàní láti wà pẹ̀lú wọn ṣùgbọ́n kò bá mi lára mu rárá.”
“Ìyẹn ni pé àwọn abo ìnàkí kìí mú ara ẹ̀ jípépé rárá bótiẹ̀jẹ́pé ìnàkí nìwọ náà?”
“Bẹ́ẹ̀ni. Bẹ́ẹ̀ gaan ni. Ó jẹ́ oun ìtìjú, ṣùgbọ́n kí n tó bojú wòkè-wolẹ̀ mo ríi pé obìnrin ènìyàn nìkan ni mo lè nífẹ̀ẹ́.”
Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì mu ìgò bíà mi tán. Mo ṣí àpò ìpápánu yẹn, mo si bùú sọ́wọ́. “Ó dàbíi pé ìyẹn lè dá wàhálà púpọ̀ sílẹ̀ o.”
“Bẹ́ẹ̀ni, wàhálà gidi gan ni. Tórípé mo jẹ́ ìnàkí, kò sí bí mo ṣe le rò pé kí abo ènìyàn máa kọbiara sí ìfẹ́ mi. Kò tiẹ̀ bójú mu rárá.”
Mo dúró dèé láti sọ̀rọ̀ síi. Ìnàkí náà fọwọ́ pa etí ẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú.
“Nítorí gbogbo èyí, mo ní láti wá ọ̀nà mìíràn láti gbé gbogbo ìfẹ́ inú mi yìí jáde.”
“‘Ọ̀nà mìíràn’ báwo?”
Ó lejú pa. Ojú ẹ̀ tó ti pupa tẹ́lẹ̀ dúdú díẹ̀ síi.
“Ẹ lè má gbà mí gbọ́” ìnàkí náà sọ. “Ẹẹ̀ tiẹ̀ ni gbà mí gbọ́ rárá, ló yẹ kí n sọ. Ṣùgbọ́n mo bẹ̀rẹ̀ sí ní jí orúkọ àwọn obìnrin tí mo nífẹ̀ẹ́ wọn.”
“Ẹ ń jí orúkọ?”
“Bẹ́ẹ̀ni. Mi ò mọ ìdí ẹ̀ ṣùgbọ́n ó dàbíi pé ẹ̀bùn kan wà tí a bí mi mọ́ tí mo máa ń lò. Tó bá wù mí, mo lè jí orúkọ ẹnìkan kí n múu di tèmi.”
Atẹ́gùn àìmòye kọ lù mí lẹ́ẹ̀kansíi.
“Mi ò rò pé ó yé mi,” mo sọ. “Ìgbà tẹ́ẹ sọ pé ẹ ń jí orúkọ èèyàn, ṣé ẹni yẹn á sọ orúkọ ẹ̀ nù pátápátá ni?”
“Rárá. Wọn ò ní sọ orúkọ wọn nù pátápátá. Oun tí mo máa ń jí ni díẹ̀ lára orúkọ wọn, ẹ̀ka kékeré. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, orúkọ náà á di yẹpẹrẹ, á fúyẹ́ ju bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ. Ó dàbíi tí sánmọ̀ bá dàbo oòrùn, tí òjìjí rẹ lórí ilẹ̀ sì ṣàfẹ́ẹ̀rí díẹ̀ síi. Ó sì tún yàtọ̀ sí irú ẹni tó bá jẹ́, wọ́n lè má mọ̀ pé wọ́n ní àdánù yìí. Wọn a kàn níran pé nǹkankan ò rí tààrà bó ṣe yẹ kó rí ni.”
“Ṣùgbọ́n àwọn kan máa ń mọ̀ abí? Wípé wọ́n ti jí díẹ̀ lára orúkọ wọn?”
“Bẹ́ẹ̀ni kẹ̀. Nígbà míì, wọn á ríi pé àwọn ò lè rántí orúkọ wọn mọ́. Èyí á ni wọ́n lára, bí èyin náa ṣe mọ̀. Wọn ò tiè ní mọ orúkọ wọn fún bó ṣe jẹ́. Nígbà mìí, ìyà ìdánimọ̀ ara ẹ̀ni á jẹ wọ́n. Gbogbo èyí sì jẹ́ ìṣe mi, nítorípé èmi ni mo jí orúkọ wọn. Èyí bà mí nínú jẹ́ gidi. Ìgbà míì ẹ̀rí ọkàn mi máa ń wúwo. Mo mọ̀ pé oun tí mo ṣe ò dáa, ṣùgbọ́n mi ò lè dáa dúró. Kìí ṣe pé mo ń pọ́n oun tí mo ṣe lé, ṣùgbọ́n ara mi máa ń yá gágá tí m bá ń ṣẹé ni. Bíi pé ohùn kan wà tó ń sọ fún mi, Eh, tẹ̀ síwájú, jí orúkọ yẹn. Kò kúkú lòdì s’ófin.”
Mo ká ọwọ́ mi gbera mo si wo ìnàkí yìí. Ara yíyá gágá? Nígbẹ̀yìn, mo sọ̀rọ̀ sókè. “Orúkọ àwọn obìnrin tí o fẹ́ràn tàbí tí o fẹ́ bá ní àjọṣepọ̀ nìkan lo máa ń jí àbí? Ṣé mo gbàá?
“Bẹ́ẹ̀ gaan ló rí. Mi ò kìí kàn ń jí orúkọ ẹnikẹ́ni.”
“Orúkọ èèyàn mélòó lo ti wá jí báyìí?”
Pẹ̀lú àròjinlẹ̀, ìnàkí náà ka gbogbo ẹ̀ lóri ìka ọwọ́ ẹ̀. Bo ṣe ń kàá, ó ń kùnsínú. Ó wòkè. “Méjẹ ni gbogbo ẹ̀. Mo ti jí orúkọ obìnrin méje.”
Ṣé eléyìí pọ̀ àbí kò pọ̀ tó? Ta ló le sọ?
“Tọọ̀, báwo lẹ ṣe máa ń jí àwọn orúkọ yìí?” Mo bèèrè. “Mo lérò pé ẹ ó fẹ́ sọ fún mi.”
“Nípa agbára èrò ọkàn nìkan ni. Agbára ìtẹjúmọ́ ẹ̀mí tí kìí sọjú lásán. Ṣùgbọ́n eléyìí ò tó. Mo máa ń nílò nǹkan tí wọ́n kọ orúkọ ẹni yẹn sí lórí. Àwọn ohun ìdánimọ dára. Káàdì ìwakọ, káàdì ọmo ilé-ìwé, káàdì adójútòfò, tàbí káàdì arìnrìnàjò. Irú àwọn nǹkan báyìí. Káàdì ìdánimọ̀ àlejò náà dára. Mo ní láti gbá irú nǹkan báyìí mú. Ní ìgbà púpọ̀, mo máa ń jí wọn ni. Jíjí ni ọ̀nà kan ṣoṣo. Gẹ́gẹ́ bí ìnàkí, mo ní ọgbọ́n púpọ̀ láti yọ́ wọ inú yàrá àwọn ènìyàn nígbà tí wọ́n bá jáde. Màá wá gbogbo ilé wọn fún oun kan tó bá lórúkọ wọn lára, màá sì múu lọ sílé mi.”
“Ẹ̀ẹ́ wá lo ohun yìí tó ní orúkọ ọmọbìnrin lórí ẹ̀, pẹ̀lú agbára ìtẹjúmọ́ yín, láti jí orúkọ wọn.”
“Bẹ́ẹ̀ni. Màá tẹjúmọ́ orúkọ tí a kọ síbẹ̀ yìí fún ìgbà pípẹ́, màá fi gbogbo èrò ara mi sórí ẹ̀, màá gba gbogbo orúkọ ẹni tí mo fẹ́ràn sínú. Ó máa ń gba àkókò púpọ̀, ó sì máa ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ara àti ẹ̀mí wá. Ó máa ń gba gbogbo ara mi, ṣùgbọ́n ó máa ṣiṣẹ́ lẹ́yìnọ̀rẹyìn — díẹ̀ lára obìnrin náà á di tèmi. Gbogbo ìfẹ́ àti èròńgbà mi, ti kò rí ibi lọ kó tó di ìgbà yìí, á wá di ṣíṣẹ.
“Ìyẹn ni pé kò sí nǹkan ìfarakanra kankan níbẹ̀?”
Ìnàkí náà kan orí mọ́lẹ̀. “Mo mọ̀ pé ọ̀bọ lásán ni mí, ṣùgbọ́n mi ò kí ń ṣe nǹkankan tí kò bójú mu. Mo máa ń mú orúkọ obìnrin tí mo fẹ́ran di ti ara mi — èyí ti tó fún mi. Mo gbà pé ìwà èyí bàjẹ́ díẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ èyí tó mọ́, tí kò sì ní fífarakàn nínú. Mo kàn fẹ́ràn ìfẹ́ ńlá fún orúkọ yẹn nínú mi ni, níkọ̀kọ̀. Bíi atẹ́gùn fẹ́rẹ́fẹ́ tó ń kọjá lórí pápá.”
“Hmm,” mo wí pẹ̀lú ìkansárá. “Bóyá a tiẹ̀ lè pe èyí ní irú ìfẹ́ ọkàn tó ga jù.”
“Mo gbà. Ó lè jẹ́ òhun ni ìfẹ́ ọkàn tó ga jù. Ṣùgbọ́n, ó tún jẹ́ àpẹẹrẹ àdánìkanwà tó le jù. Bíi òdì méjì ìlù gángan. Ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀tọ̀ tí a sopọ̀ tí a kò lè pín níyà.”
Ìtakùrọ̀sọ wa parí síbẹ̀yẹn, èmi àti ìnàkí yìí bá ń mu bíà wa nínú ìdákẹ́jẹ́, a sì ń jẹ Kapipi wa àti ìṣáwùrù gbígbẹ̀.
“Ǹjẹ́ e ti jí orúkọ ẹnìkankan láìpẹ́ yìí?” Mo bèèrè.
Ìnàkí náà mi orí ẹ̀. Ó gbá díè mú nínú àwọn irun tó dìde lápá ẹ̀, bíi pé ó fẹ́ ríi dájú pé ìnàkí lòun. “Rárá, mi ò tíì jí orúkọ ẹnìkankan láìpẹ́. Nígbà tí mo wá sí ìlú yìí, mo pinnu láti dẹ́kun gbogbo irú ìwà pálapàla yẹn. Nítorí èyí, ọkàn ìnàkí kékeré yìí ti rí àláfíà díẹ̀. Mo tọ́jú orúkọ àwọn obìnrin méje tó wà nínú ọkàn mi, mo sì ń gbé ìgbé ayé ìdákẹ́jẹ́ àti ìbàlẹ̀ ọkàn.”
“Inú mi dùn láti gbọ́ èyí,” mo dáhùn.
“Mo mọ̀ pé ẹ lè rò pé mo yájú, ṣùgbọ́n mo fẹ́ bèèrè bóyá ẹ lè jẹ́ kí n sọ èrò tèmi nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́.”
“Ẹ sọọ́,” mo fèsì.
Ìnàkí náà ṣẹ́jú pòròpòrò láìmọye ìgbà. Ìpéǹpéjú ẹ̀ gígùn lọ sókè-sílẹ̀ bí imọ̀ ọ̀pẹ nínú atẹ́gùn. Ó mí sínú-síta bí irú èyí tí asáréìje máa ń mí sínú kó tó bẹ̀rẹ̀ eré sísá.
“Mo gbàgbọ́ pé ìfẹ́ jẹ́ bí epo àìleṣaláìmánìí tó ń gbà wá láàyè láti máa gbé ilé ayé lọ. Lọ́jọ́ kan, ìfẹ́ yìí lè dópin. Ó tiẹ̀ lè má já mọ́ nǹkankan. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ìbáà tiẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì, kódà bí a kò bá fẹ́ ni padà, a sì tún lè di ìrántí mú pé a ti nífẹ̀ẹ́ rí, wípé a ti wà nínú ìfẹ́ pẹ̀lú ẹnìkan rí. Èyí sì jẹ́ orísun ìmóríyá tó péye. Láìsí orísun oríyá yìí, ọkàn ẹnìkan — tàbí ọkàn ìnàkí pẹ̀lú — á di aginju olótùútù ìkorò. Ibi tí ìtànsán òòrùn kankan kìí dé, níbi tí àwọn irúgbìn ìbàlẹ̀ ọkàn, igi ìrètí, kò ti ní ààyè láti wù. Mo ṣètọ́jú àwọn orúkọ àwọn obìnrin arẹwà méje tí mo ti fẹ́ràn yìí nínú ọkàn mi.” Pẹ̀lú èyí, ìnàkí láà gbé àtẹlẹwọ́ ẹ̀ sórí àyà. “Mo pinnu láti lo àwọn ìrántí yìí gẹ́gẹ́ bí orísun epo kékeré tèmi láti jó láwọn alẹ́ olótùútù kó baà lè mú mi gbóná nígbà tí mo bá ń gbé èyí tó kù ìgbésí ayé tèmi.”
Ìnàkí náà rẹ́rìín ìyàngì lẹ́ẹ̀kansíi, ó sì mi orí ẹ̀ fẹ́rẹ́fẹ nígbà díẹ̀ síi.
“Ǹjẹ́ ọ̀nà tí mo fi sọọ́ ò ya ni lẹ́nu díẹ̀ bi?” ó wi. “Ìgbésí ayé ara ẹni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìnàkí ni mí, mi kìí ṣe ènìyàn. Hee hee…”
AAGO MỌ́KÀNLÁ ÀÀBỌ̀ ni a parí ìgò ńlá méjì ọtí bíà wa. Ó yẹ kí n máa lọ ilé báyìí, ìnàkí náà sọ. “Àfi bíi pé ọtí náà dùn mọ́ mi nínú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní janu bí ejò, ẹ má bìínú.”
“Rárá, mo gbádùn ìtàn yẹn gaan ni,” mo dáhùn. Bóyá gbígbádùn kọ́ ni ọ̀rọ̀ tó yẹ kí n lò. Àbí, pípín ọtí bíà àti títàkurọ̀sọ pẹ̀lú ìnàkí ṣá jẹ́ oun méríìírí. Ká má ṣẹ̀ wá sọ pé ìnàkí yìí pàápàá fẹ́ràn Bruckner, ó sì máa ń jí orúkọ àwọn obìnrin nítorípé ó fẹ́ bá wọn l’ájọṣepọ̀ (àbí nítorí ìfẹ́ ọkàn). Gbígbádùn ò tiẹ̀ tó láti ṣàpéjúwe ẹ̀. Ó jẹ́ oun tó yanilẹ́nu jù tí mo ti gbọ́ rí. Ṣùgbọ́n nítorípé mi ò fẹ́ gbé ọkàn ìnàkí yìí sókè ju bó ti yẹ lọ ni mo ṣe lọ ọ̀rọ̀ yìí tí mo rò pé ó jẹ́ èyí tó tu ni lára tí kò sì mú ìṣègbè dání.
Bí a ṣe juwọ́ sí ara wa, mo fún ìnàkí yìí ní ¥1,000 gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. “Kò tó ǹkan ṣùgbọ́n jọ̀ọ́ fi ra nǹkan gidi fúnra rẹ láti jẹ.”
Lákọ̀ọ́kọ́, ìnàkí yìí kọ̀, ṣùgbọ́n mo yarí. Ìgbá tó yá, ó gbàá. Ó ká owó náà ó sì fi pẹ̀lẹ́kùtù fi sínú àpo aṣọ ẹ̀.
“Onínúure ni yín,” ó sọ. “Ẹ ti gbọ́ ìtàn ayé mi bó ṣe yanilẹ́nu tó, ẹ fún mi lọ́tí mu, ẹ tún wá ṣe oore tó tó báyìí. Mi ò lè sọ tán bí mo ṣe moore yín tó.”
“Ìnàkí bá fi àwọn òfìfo ìgò bíà àti ife ìmutí sílẹ̀ lórí pẹpẹ ìṣàlejò, ó sì gbée jáde kúrò nínú yàrá.
LỌ́JỌ́ KEJÌ, mo kó jáde nínú ilé ìtura náá̀, mo sì padà sí Tokyo, ṣùgbọ́n mi ò rí ìnàkí yìí níbìkankan. Níbi ìsanwó, mi ò rí ọkùnrin arúgbó yẹn tí kò nírun orí tàbí t’ìpéǹpéjú. Mi ò sì rí ológbò arúgbó alárùn nímú yẹn. Dípò ẹ̀, obìnrin abílékọ kan tó sanra tojú ẹ̀ kọ́rẹ́lọwọ́ ló wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n ìgbà tí mo sọ fúun pé mo fẹ́ sanwó èlé fún ọtí alẹ́ àná, ó sọ pẹ̀lú ìgboyà pé kò sí èlé owó lóri oun tí mo ní láti san. O tẹnu mọ́ọ pé gbogbo oun tí a ní níbi kò ju owó bíà inú agolo kan tí a gbà láti inú ẹ̀rọ atajà lọ. A ò kí ń ta bíà inú ìgò níbí.
Lẹ́ẹ̀kansíi, gbogbo ẹ̀ dàrú mọ́ mi lójú. Ó dàbíi wípé oun tí mo mọ̀ àti oun mèremère ti ń dàpọ̀ mọ́ra wọn lójú mi. Mo mọ̀ dájú pé mo pín ìgò ńlá ọtí bíà Sapporo méjì mu pẹ̀lú ìnàkí yìí bí mo ṣe ń gbọ́ ìtàn ayé ẹ̀.
Mo fẹ́ bèèrè nípa ìnàkí yẹn lọwọ́ abílékọ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n mo pinnu láti má ṣe bẹ́ẹ̀. Bóyá ìnàkí yìí ò tiẹ̀ sí rárá, bóyá mo kàn ṣìrànrán ẹ̀ ni, nítorípé ọpọlọ mi ti dúró pẹ́ jù nínú omi onísun-gbígbóná yẹn. Tàbí nǹkan tí mo rí jẹ́ àlá lásán ni, tó gùn, tó ṣe méríìírí, tó sì dàbí oun ojúlówó. Nítorínáà, tí mo bá sọ nǹkan bíi “Ǹjẹ́ ẹ ò ní òṣìṣẹ́ kan tó jẹ́ ìnàkí àgbàlagbà tó ń fọhùn bí ènìyàn bi?” nǹkan lè doríkodò. Wọ́n tiẹ̀ tún lè rò pé mo ya wèrè ni. Àlàyé mìí tún ni pé ìnàkí yìí jẹ́ òṣìṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ kan tí wọn ò forúkọ ẹ̀ sórí ìwé, ilé ìtura náà ò sì lè dárúkọ ẹ̀ ní gbangba kí àwọn ilé iṣẹ́ agbowó-orí tàbí ilé iṣẹ́ ìlera má baà gbọ́ nípa ẹ̀ — èyí tó jẹ́ oun tó lè ṣẹlẹ̀.
Nínú ọkọ̀-ojú-irin tí mo wọ̀ padà sílè, mo tún gbogbo oun tí ìnàkí yìí sọ fún mi gbọ́ lórí mi. Mo kọ gbogbo oun tó ṣe pàtàkì níbẹ̀ sílẹ̀, bí mo ṣe rántí wọn tó, sínú ìwé pélébé tí mo ń lò fún iṣẹ́, lérò pé tí m bá dé Tokyo, màá kọ gbogbo ẹ̀ sílẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ d’ópin.
Tí ìnàkí yìí bá wà nítòótọ́ — ọ̀nà kan ṣoṣo tí mo lè ti ríi náà nìyí — mi ò mọ mélòó ni kí n gbàgbọ́ nínú àwọn ohun tó sọ fún mi nígbà tí a ń mu ọtí bíà. Ó le láti ṣèdájọ́ ẹ̀ láìṣègbè. Ṣé èyí tiẹ̀ lè ṣeéṣe bí? Láti jí orúkọ àwọn obìnrin àti láti múu di tara ẹni? Ṣé èyí jẹ́ irú agbára kan tí àwọn ìnàkí Shìnágáwà nìkan ní ni? Àbí onírọ́ paraku ni ìnàkí yìí? Ta ló le sọ? Èmi fúnra mi ò tíì gbọ́ nípa ìnàkí tó ní àrùn aìlesòótọ́ rí, ṣùgbọ́n ṣebí tí ìnàkí bá ti le sọ̀rọ̀ èdè ọmọ ènìyàn lọ́nà tó jáfáfá bí ìnàkí yìí ṣe ń sọọ́, kò le láti ròó pé ó tún lè jẹ́ òpùrọ́ gidi.
Nínú iṣẹ́ mi, mo ti fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́nu wò, mo si ti mọṣẹ́ dáadáa dé’bi pé mo lè mọ ẹni tó tọ́ láti gbàgbọ́ àti ẹni tí kò tọ́. Tí èèyàn kan bá ti sọ̀rọ̀ fún ìgbà díẹ̀, wàá ti rí àwọn nǹkankan kékèké gbámú, irú àwọn ààmì tí ọkùnrin (tàbí obìnrin) náà ń fi ránṣẹ́, wàá sì ti mọ̀ bóyá wọ́n ṣeé gbàgbọ́ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Mi ò ṣá ríi gbàgbọ́ pé oun tí ìnàkí Shìnágáwà yìí jẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀. Bí mo ṣe wo ojú ẹ̀, àti bó ṣe ń sọ̀rọ̀, bó ṣe ń ronú nǹkan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìdákẹ́jẹ́ ẹ̀, ìfapásọ̀rọ̀, gbogbo bó ṣe máa ń kálòlò láti rí ọ̀rọ̀ sọ—kò sí nǹkankan nípa ẹ̀ tó dàbí àhesọ tàbí oun afipáṣe. Lẹ́yìn èyí ni bí ìjẹ́wọ́ yìí ṣe jẹ́ oun ẹ̀dùn káríkárí, àti bó ṣe fara jọ òótọ́ tó.
Ìrìn àjò àdánìkanrìn mi ti parí báyìí, mo wá padà si ìrìnkèrindò inú ìlú. Láì tiẹ̀ sí iṣẹ́ mìíràn kankan láti ṣe mọ́, bí mo ṣe ń dàgbà síi ni ọwọ́ mi ń kún síi. Àsìkò sì dàbí ẹni tó ń sáré tete. Nígbẹ̀yìn mi ò sọ fún ẹnìkankan nípa ìnàkí Shìnágáwà, mi ò sì kọ nǹkankan nípa ẹ̀. Kí l’àǹfààní kikọ nǹkan nípa ẹ̀ nígbà tí kò s’ẹ́ni tá gbà mí gbọ́? Àwọn èèyàn á kàn máa sọ pé mo ti ń “sọ ìsọkúsọ” ni. Mi ò tiẹ̀ tún mọ irú ọ̀nà tí màá fi kọọ́. Ó jẹ́ oun kàyéfì láti kọ gẹ́gẹ bí oun tó ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́, nítorípé kò sí bí mo ṣe lè fi ẹ̀rí hàn—ẹ̀rí wípé ìnàkí yìí wà ní tòótọ́. Kò sí ẹni tó máa gbàágbọ́. Bí mo bá tiẹ̀ kọọ́ gẹ́gẹ́ bí ìtàn àròsọ, kò ní lórí tàbí ìdí. Kí n tiẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí kọọ́ ni mo ti rí ojú olùtẹ̀wé mi pẹ̀lú ìpòrúurùu nígbà tó bá kàá tán, pẹ̀lú ìbéèrè ẹ̀ tó máa tẹ̀lée: “Kò yẹ kí n máa bèèrè èyì lọ́wọ́ ẹ nítorí pé ìwọ ni olùkọ̀wé, ṣùgbọ́n — kíni kókó ìtàn yìí gaan na?”
Kókó? Mi ò lè sọ pè ìkan wà níbẹ̀. Ẹ ṣá mọ̀ pé ó jẹ́ ìtàn ìnàkí kan tó ń sọ èdè ènìyàn nínú ìlú kékeré kan ní agbègbè Gunma, tó máa ń fọ ẹ̀yìn àwọn àlejò nínú ilé ìwẹ̀ gbígbóná, tó máa ń gbádùn bíà tútù, tó máa n nifẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ènìyàn tó sì máa ń jí orúkọ wọn. Kíni kókó inú ìyẹn? Tàbí ẹ̀kọ́?
Bí àsìkò ṣe ń lọ sí, ìrántí ìlú onísun-gbígbóná yìí bẹ̀rẹ̀ sí parẹ́ lọ́kàn mi. Bo tile wù kí ìrántí kan le lọ́ọ̀rìn tó, wọn kò lè sáré ju agbára àsìkò lọ.
ṢÙGBỌ́N NÍ BÁYÌÍ, lẹ́yìn ọdún márùún, mo ti pinnu láti kọ nípa ẹ̀, pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ kékèké tí mo fi sínú ìwé pélébé mi nígbàyẹn. Ìdí èyi ni oun kan tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí tó mú mi rántí. Tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò bá ṣẹlẹ̀ ni, m̀bá tí kọ oun tí ẹ ń kà lọ́wọ́ yìí.
Lọ́jọ́ kan, mo ní ìpàdé iṣẹ́ kan nínú yàrá ìgbàlejò ilé ìtura kan ní Akasaka. Ẹni tí mo ń pàdé jẹ́ olùdarí ìwé ìròyìn arìnrìnàjò kan. Ó jẹ́ obìnrin tó rẹwà gidi, bí ọmọ ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò lára púpọ̀, ṣùgbọ́n ó ní irun gígùn, àwọ ara tó lẹ́wà, pẹ̀lú ojú ńlá tó fanimọ́ra. Ó sì tún jẹ́ olùṣàkóso ìtẹ̀wé tó moṣẹ́. Kò lọ́kọ. A ti ṣiṣẹ́ papọ̀ nígbà díẹ̀ rí, a sì mọwọ́ ara wa. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti parí iṣẹ́ wa, a fẹ̀yìntì, a sì tàkurọ̀sọ díẹ̀ tí a sì ń mu kọfí.
Fóònù alágbèéká ẹ̀ dún, ó sì wò mí bí ẹni ń bẹ̀bẹ̀. Mo ní mi ò bínú, pé kó gbé ìpè náà. Ó dàbíi pé ìpè náà wà nípa ààyè tó gbà sílẹ̀ níbìkan, bóyá nílé oúnjẹ, tàbí ilé ìtura, tàbí ti ìrìnnà òfurufú. Irú nǹkan báyìí ni. Ó sọ̀rọ̀ fún ìgbà díẹ̀, ó sì ń wo ìwé pélébé abániṣẹ̀tò ẹ. Ó wá wò mí pẹ̀lú ojú ìpòrúurùu.
“Má bìnú o,” ó sọ fún mi pẹ̀lú ohùn ìṣàlẹ̀, ó sì fi ọwọ́ bo ẹnu fóònù. “Mo mọ̀ pé ìbéèrè yìí yanilẹ́nu o, ṣùgbọ́n kíni orúkọ mi?”
Ọkàn mi fò sókè, ṣùgbọ́n mo sọ orúkọ ẹ̀ fúun lákòótán, àti lọ́nà tí kò mú ìfura kankan wá. Ó gbọ́, ó sì sọ èyí fún ẹni tó wà lódìkejì fóònù yìí. Ó parí ìpè yìí, ó sì tọrọ àforíjì lọwọ́ mi.
“Má bìnú o. Mo kàn gbàgbé orúkọ mi lójijì ni. Ó ya èmi gaan lẹ́nu.”
“Ṣé èyí máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀kan ni?” Mo bèèrè.
Ó ṣebí ẹni pé ó ń ronú nípa ẹ̀, ṣùgbọ́n ó padà gbá pé “Bẹ́ẹ̀ni, ó ti máa ń ṣẹlẹ̀ púpọ̀ lẹ́nu ijọ́ mẹ́ta yìí. Màá kàn gbàgbé orúkọ mi; bíi pé iyè mi sọnù lójijì ni.”
“Ṣé o máa ń gbàgbé àwọn nǹkan mìíì? Bíi kóo má le rántí ọjọ́ ìbí ẹ, tàbí nọ́mbà fóònù ẹ, tàbí nọ́mbà PIN?”
Ó mirí ẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú. “Rárá o. Iyè mi sọ dáadáa. Mo mọ gbogbo ọjọ́ ìbí àwọn ọ̀rẹ́ mi lórí. Mi ò tiẹ̀ tíì gbàgbé orúkọ ẹnìkankan rí lẹ́ẹ̀kanṣoṣo. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìgbà míì, mi ò kí ń rántí orúkọ tèmi gangan alára. Ó jẹ́ oun kàyéfì. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, iyè mi á sọ padà, ṣùgbọ́n àwọn ìṣẹ́jú kékeré tí mi ò fi rántí yẹn ló le jù. Ẹ̀rù máa ń bà mí, bíi pé mi ò dá ara mi mọ̀ mọ́ ni.”
Mo kanrí mọ́lẹ̀ láìsọ̀rọ̀.
“Ṣé o rò pé èyí túmọ̀ sí pé mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ṣí ṣ’arán ni?”
Mo mí kanlẹ̀. “Ká sọ pé ti ètò ìlera ni, èmi ò mọ̀. Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni ó bẹ̀rẹ̀ — gbogbo àwọn ààmì tí o dárúkọ yìí, nípa gbígbàgbé orúkọ?”
Ó dínjú, ó sì ròó díẹ̀. “Mo rò pé bíi oṣù mẹ́fà sẹ́yìn ni. Mo rántí pé ó jẹ́ ìgbà tí mo lọ gbàdùn àwọn òdòdó ṣẹrí níta, ni mi ò bá rántí orúkọ mi mọ́. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́.”
“Má bìnú tí ìbéèrè mi bá dàbí òdì ọ̀rọ̀ o, ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o sọ nǹkankan nù lásìkò yẹn? Nǹkan bíi káàdì ìdánimọ̀, bíi ìwé ìwakọ̀, ìwé ìdánimọ̀ ìrìnà òfurufú, tàbí káàdì adójútòfò?”
Ó ṣu ẹnu ẹ̀, ó ronú fún ìgbà díẹ̀, ó sì fèsì.
“Bóo ṣe dárúkọ ẹ̀ yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ mú mi rántí ni pé mo sọ ìwé ìwakọ̀ mi nù nígbà yẹn. Àsìkò oúnjẹ ọ̀sán ni, mo dẹ̀ jókòó sí oríi pèpéle ìta gbangba, mo ń gbatẹ́gùn. Mo gbé báàgì ìgbékọ́pá mi sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi lórí pèpéle ọ̀hún. Mo ń tún ìtọ́tè mi kùn pẹ̀lú dígií. Ṣùgbọ́n ìgbà tí mo máa wo ẹ̀gbẹ́ mi, báàgì mi ti lọ. Kò yé mi rárá. Kò tó ìṣẹ́jú àáyá kan tí mo fi gbójú kúrò níbi báàgì ọ̀hún, mi ò sì níran ẹnìkankan láyìíká, tàbí gbọ́ ìró ẹsẹ̀ kankan. Mo wò yíká ibẹ̀, ṣùgbọ́n èmi nìkan ni mo wà ńbẹ̀. Ibẹ̀ jẹ́ pápá tó dákẹ́jẹ́ẹ́, ó sì dá mi lójú pé tí ẹnìkankan bá wá síbẹ̀ láti jí báàgì mi lọ, màá ti kófìrí ẹ̀.
Mo dúró dèé láti tẹ̀síwájú.
“Ṣùgbọ́n eléyìí nìkan kọ́ ló ṣe kàyéfì o. Lọ́sàán ọjọ́ yìí gangan, mo gba ìpè kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá wípé wọ́n ti rí báàgì alágbèéká mi. Ẹnìkan ti gbée sílẹ̀ síwájú àgọ́ ọlọ́pàá kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ pápá yẹn. Kò sí nǹkan mìíràn tó sọnù níbẹ̀ o — gbogbo owó ṣì wà nínú ẹ̀, pẹ̀lú gbogbo káàdì ìyáwó mi, káàdì ìgbowórìn, àti fóònù àgbérìn. Gbogbo ẹ̀ wà níbẹ̀ láìfọwọ́kàán. Káàdì ìwakọ̀ mi nìkan ló sọnù. Òun nìkan ni oun tí wọ́n jímú nínú báàgì mi. Kò dàbí oun tí èèyàn lè gbàgbọ́, kódà ó ya ọlọ́pàá gan lẹ́nu. Wọn kò mú owó, wọ́n mú káàdì ìwakọ̀, wọ́n sì gbé báàgì ọ̀hún sílẹ̀ níwájú àgọ́ ọlọ́pàá.
Mo tún mí kanlẹ̀ jẹ́jẹ́, mi ò sọ nǹkankan.
“Ìparí oṣù kẹta nìyí o. Lójú ẹsẹ̀, mo lọ sí ilé iṣẹ́ Ìrìnnà Ọkọ̀ ní Samezu, wọ́n sì fún mi ní ìwé ìrìnnà ọkọ̀ mìíì. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yà mí lẹ́nu gidi, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé kò sí ewu kankan tó tibẹ̀ jáde. Samezu ò sì jìnnà sí ibi iṣẹ́ mi, nítorínáà kò gba àsìkò púpọ̀.”
“Shìnágáwà ni Samezu wà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?”
“Bẹ́ẹ̀ni o. Ó wà ní Higashioi. Ilé iṣẹ́ mi wà ní Takanawa, nítorí náà, ó jẹ́ ibi tí mo kàn lè wọ takisí lọ ní kíá,” ó sọ. O wá fojú ẹ̀gbẹ́ kan wò mí. “Ṣé o rò pé wọ́n tan mọ́ ara wọn ni? Bí mi ò ṣe rántí orúkọ mi mọ́ àti sísọ ìwé ìrìnnà ọkọ̀ mi nù?”
Mo mi orí mi ní kíákíá. Mi ò lè gbé ọ̀rọ̀ ìnàkí Shìnágáwà wá síbi o. Tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè máà bèèrè pé níbo ló wà báyìí, kó wá lọ kòó lójú nílé ìtura náà, kó máa bèèrè gbogbo oun tó ṣẹlẹ̀.
“Rárá, mi ò rò pé wọ́n tan mọ́ ara wọn,” mo fèsì. “Ó kàn wá sí mi lọ́kàn láti bèèrè ni, nítorípé o jọ mọ́ orúkọ ẹ ni.”
Kò dà bíi ẹni tó gbà mí gbọ́. Mo mọ̀ pé ó léwu ṣùgbọ́n ìbéèrè pàtàkì kan ṣẹ́kù tí mo ní láti bèèrè.
“Tiẹ̀ gbọ́ ná, ǹjẹ́ o ti rí ìnàkí kankan lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí?”
“Ìnàkí?” Ó bèèrè. “Ṣé ọ̀bọ lágídò ẹranko?”
“Bẹ́ẹ̀ni, ìnàkí ẹranko,” mo dáhùn.
Ó mi orí ẹ̀. “Mi ò rò pé mo ti rí ìnàkí kankan fún ọdún pípẹ́, bóyá ní ọgbà ẹranko tàbí níbòmíì.”
ÀBÍ ÌNÀKÍ SHÌNÁGÁWÀ YÌÍ ti padà sí ìwà ìpátá ẹ̀ ni? Àbí ìnàkí mìíràn ló ń lo àwọn ọgbọ́n àyínìke ẹ̀ láti ṣe àwọn ìrúfin yìí ni? (Ọ̀bọ afìwàjọraẹni!) Àbí nǹkan mìí, tí kì ń ṣe ìnàkí yìí, ló ṣokùnfàá ni?
Mi ò ṣá fẹ́ gbà pé ìnàkí Shìnágáwà yìí lo ti padà sí jíjí orúkọ àwọn èèyàn. Ṣèbí ó ti sọ fún mi ní pàtó pé dídi orúkọ àwọn obìnrin méjẹ mú sínú òun ti tó gẹ́ẹ́, pé inú òún máa dùn láti kàn máa gbé ìyókù ayé oun lálàáfíà nínú ìlú onísun-gbígbóná yẹn ni. Ó sì dàbíi pé ó dáa lójú. Àbí bóyá ìnàkí yìí ní àrùn kan tí kò gbóògùn, tí èèyàn ò lè fi ìrònú lásán yí padà. Àti pé bóyá àìsàn ẹ̀, àti ìjípépé ara ẹ̀, ló ń sọ fúun pé kó ṣá máa ṣeé lọ! Bóyá gbogbo èyí ló mú padà wá sí àdúgbọ̀ ẹ̀ àtijọ́ ní Shìnágáwà, padà sí ìwà ìbàjẹ́ ẹ̀ àtijọ́ tó kọ̀ tí kò lọ.
Bóyá màá tiẹ̀ gbìyànjú ẹ̀ níjọ́ kan fúnra mi. Láwọn òru aláìróorunsùn kọ̀ọ̀kan, lọ́jọ́ tí àwọn ìrònú onírúurú aládùn bá ń wá sí mi lọ́kàn. Màá wá káàdì ìdánimọ̀ tàbí káàdì orúkọ ìtẹ̀mọ́ra obìnrin kan tí mo fẹ́ràn, màá tẹjú mọ́ọ dáadáa, màá gba gbogbo orúkọ ẹ̀ sínú mi, màá wá gba díẹ̀ lára ẹ̀ wá fún ara tèmi nìkan. Báwo ló ṣe máa rí na? Rárá, kò tiẹ̀ lè ṣẹlẹ̀. Ọwọ́ mi ò yá báyẹn, mi ò sì ní lè jí nǹkan tó jẹ́ t’ọmọ ẹlòmìíràn. Nǹkan ọ̀hún ìbáà jẹ́ oun tí kò ṣeé rí dìmú. Jíjalè sì jẹ́ oun tó lòdì sófin.
Ìfẹ́ alágídí, ìdánìkanwà àìlópin. Láti ìgbà yẹn, ìgbàkúùgbà tí mo bá tẹ́tí sí orin Bruckner, mo máa ń rántí ìgbésí ayé ìnàkí Shìnágáwà yẹn. Mo máa ń níran ìnàkí àgbàlagbà kan nínú ìlú onísun-gbígbóná yẹn, nínú àjà ìlé ìtura àlàpà kan, tó daṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ bora, tó sì sùn. Màá sì máa rántí àwọn ìpanu ibẹ̀—Kakipi àti ìṣáwùrù gbígbẹ—tí a gbádùn nígbà tí a ń mu ọtí bíà papọ̀, tí a sì f’ẹ̀yìn ti ògiri.
Mi ò tíì rí obìnrin arẹwà atọ́kùn ìwé ìròyìn arìnrìnàjò mi yen mọ́ láti ọjọ́ yìí, nítorínáà mi ò mọ oun tó ṣẹlẹ̀ sí orúkọ ẹ̀. Mo ṣá rò pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò fúun ní ìdààmú púpọ̀ kankan rárá. Òun ò ṣáà l’ẹ́bi kankan níbẹ̀. Òun kọ́ ló fa èyíkéyìí nínú gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀. Ó máa ń mú inú mi bàjẹ́ ṣá, ṣùgbọ́n mi ò lè mú ara mi wá látí sọ fúun, nípa ìnàkí Shìnágáwà yẹn.
_______
Kọ́lá Túbọ̀sún is the founder/publisher of OlongoAfrica. A Nigerian linguist and poet, author of Edwardsville by Heart and Ìgbà Èwe, he lives in Lagos, Nigeria. He can be found at kolatubosun.com
“Shinagawa zaru no kokuhaku (Confessions of a Shinagawa Monkey)” from ICHININSHO TANSU (First Person Singular). Copyright © 2020 Harukimurakami Archival Labyrinth. Originally published by Bungeishunju Ltd., Tokyo.
_______
Illustrations by Yẹ́misí Aríbisálà